BÍ O ṢE LE ṢÀFỌ̀MỌ́ KÍDÌNRÍN RẸ PẸ̀LÚ ÌRỌ̀RÙN

Bí ọdún ti ń gorí ọdún, tí àwọn kídìnrín wa ń sẹ́ ẹ̀jẹ̀ ara wa, láti le yọ iyọ̀ àti àwọn ohun olóró tó le ṣe àgọ́ ara wa ní jàǹbá kúrò.
Iyọ̀ a máa gbilẹ̀ nínú àgọ́ ara wa bí ọdún ṣe ń gorí ọdún, èyítí yóò sì nílò àfọ̀mọ̀.
* Ọ̀NÀ LÁTI ṢE ÈYÍ
Já efinrin sínú abọ́, kí o fi omi tó mọ́
sàn-án dáradára, gé e bí o bá fẹ́, da jálá omi kan sínú rẹ̀, kí o sì sèé lórí iná fún ìṣẹ́jú mẹ́wàá. Lẹ́yìn èyí, sọ̀ọ́ kalẹ̀, jẹ́kí ó tutù, fi asẹ́ sẹ omi kúrò lára ewé. Omi yìí gan-an loògùn abẹnu gọ̀ǹgọ̀.
O le gbé e sínú ẹ̀rọ amóhuntutù, kí o sì máa mu gàásì kan lójúmọ́. Láìpẹ́ ọjọ́, wàá ríi tí àwọn iyọ̀ tó lúgọ sínú àgọ́ ara rẹ àtàwọn ohun olóró mìíràn tó ti jẹ gàba sínú kídìnrín rẹ yóò máa bá ìtọ̀ jáde.
Èyí jẹ́ ọ̀nà kan gbòógì láti fọ kídìnrín wa mọ́ tónítóní. Kò ná ‘ni ní wàhálà, bẹ́ẹ̀ sìni, ó fẹ́rẹ̀ má ná ènìyàn l’ówó.
Pín ìlanilọ́yẹ̀ yí pẹ̀lú àwọn ẹbí àtọ̀rẹ́, nítoríwípé a kò mọ ẹni tí yóó kàn, tó le kàn wá. Láburú ò níí kángun sọ́dẹ̀dẹ̀ wa láṣẹ Èdùmàrè 🙏
©️YORÙBÁ KAN

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *