Atanda ọmọ Ibironke

Imujade lati Inu ise Iwadi Ijinle Omoba Adeyemi Olabimpe (Akojopo ati tite lati owo alamojuto oro iroyin arakun Oladotun Oladele 08037250845)


Awon eya Yoruba ti o síde lẹ́yìn tí Odùduwà ti fìdí múlẹ sí Ilé-ifẹ̀ pọ̀ púpọ̀. Lára won ni Òwu, Ọ̀yọ́, Kétu, Ẹ̀gbá, Ìjẹ̀bú, Ìjẹ̀ṣà , Sábẹ̀ẹ́, Pópó, Ìgbómìnà abbi. Ohun kan ti a saba fi da eya kan mo sí òmíràn, ni agbegbe ibi to won tedo si, ede abinibi ti won n so, ise to wopo laarin won ti won n se, Orisa to fidii mule laarin won ti won n bọ, oúnjẹ ti won n jẹ ati ohun ọ̀gbìn tí won n saba gbin pẹ̀lú ìhùwà ati ìbágbépọ̀ won.


Ninu gbogbo eya tabi ijoba Ile Yoruba, eyi ti o tobi ju ni Ọ̀yọ́. Ọ̀rànmíyàn ti o tẹ Ọ̀yọ́ do jẹ jagunjagun, Ìkannìkò, Oloogun ati Akanda eniyan gẹ́gẹ́ bíi Odùduwà. Itan so fun ni pe, oun naa jade kuro ni Ile-Ife, o si gun esin jade ni ati pe, Ifa ni ibi ti ese esin re ba yo ni ki o tedo si, ibi ti esin re ti yo yii ni a n pe ni “Ọ̀YỌ́“. Ni iha iwo-oorun, Ọ̀rànmíyàn ni a ri ti o se bi i baba rẹ tí ó lè pa gbogbo awon ilu kéréje abẹ́ rẹ̀ pọ̀ sí abẹ́ ìjọba kan soso tíí se tiẹ̀.



Adeoye (1979) ni, Ọ̀rànmíyàn ni o Koko da Ẹ̀ṣọ́ sílẹ̀, oun si ni olori awon Ẹ̀sọ́ ni ile Yoruba ni akoko tie. O fi kun un pe, nitori ti o je olori awon Eso yi ati jagunjagun ti o kaju osuwon ni afefe yeye awon Oyo se po, eyi ni won si fi maa nse yanga si awon omo baba won yooku, ti won maa n powe pe “A-ji-se-bi-Oyo la a ri, Oyo ki i se bi enikan”. Titi di oni ni okiki Oranmiyan kan ni ile-Ife koda bi a ba ti mu odun Oduduwa sise kuro ni Ife tan, odun ti o tun se pataki bi i ti Oranmiyan ko si mo ni aarin awon Yoruba.



Kete ti Ọ̀rànmíyàn de Ọ̀yọ́-Ilé ni o yan awon Ìwàrẹ̀fà, awọn mẹ́fẹ́ẹ̀fà ohun naa ni Basọ̀run, Àgbaakin, Sàmù, Alápìńni, Lágùnà ati Akinnikú. Nigba ti o ya ni oruko yii awon Iwarefa yii si yipada di “Ọ̀yọ́-mèsì” asiko naa si ni awon Ìwàrẹ̀fà yii kuro ni mẹfa ti won di méje pẹ̀lú àfikún “Asípa“.



J.F.A. Ajayi ati S.A. Akintoye (1980) so pe, àgbàrá Ọ̀yọ́ pọ lasiko naa debi pe, ki i se Ile Ọ̀yọ́ nikan ni o lagbara le Lori, o tun lagbara lori awon ilu ti o wa lagbegbe re ati awon ti o báa pààlà bíi Bọ̀rgú, Núpé, Ẹ̀gbá ati Ẹ̀gbádò, Dàhòmì pẹlu Pọtu-Nófò (Porto-Novo). Ọna ti o se pataki ju ti awon onisowo lati Bini si Ọ̀wọ́, Àkúrẹ́ lọ si Naija n gba si tun kọja si Ọ̀yọ́.



Eyi waa je ki o jẹ́ pé, ninu gbogbo Ilẹ Yorùbá pàápàá ni ibẹrẹ senturi kokandilogun (19th century), won gba Ifẹ̀ gẹ́gẹ́ bí orírun Yorùbá ati paapaa Ilé awon ti o te Ilẹ Yorùbá dó. Won fun Ọ̀yọ́ ni Ọ̀wọ́ pupo nitori àgbàrá ati owo ti won ni lasiko naa, ati pelu eto ìṣèjọba won ti o múná dóko ti o si f’ẹsẹ̀ rinlẹ̀ gbingbin.


Nigba ti o se, àgbàrá Ọ̀yọ́ pọ debi pe o sòro fún Aláàfin lati sakoso ilu ọ̀hún, awon ijoye ko dun un sèjọba le lori mo, o si soro fun Ọba lati fokan tan won dénú. Akínjọ̀gbìn (1966) jẹ ki o yeni pe, pelu bi Aláàfin ati awon Ìjòyè ko se gbọ ara won yé yìí fi Ààyè silẹ fun ọ̀tẹ̀ láti wọ inú ìjọba Ọ̀yọ́, sé bí ògiri ko ba lanu, aláǹgbá ko le raye wọ ọ.



Gbogbo ọgbọn ati òye láti paná awon aáwọ̀ yi ja si pabo, eyi si je ki ogun raye ja Ọ̀yọ́, ọ̀tẹ̀ ati tẹ̀m̀bẹ̀lẹ̀kun wọlé, ìlú Ọ̀yọ́ si tu ni eyi ti o mu ki ijoba Ọ̀yọ́ sípòpadà si Ọ̀yọ́-Ìgbòho. Aláàfin mẹrin ni o jẹ ni ilu Ọ̀yọ́-Ìgbòho, awon mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ni won si sun si ibi ti a n pe ni “Igbó-Ọba” ni ilu ohun bayii. Oruko awon Alaafin naa ni Aláàfin Òfinràn, Aláàfin Egun-ojú, Aláàfin Ọ̀rọ̀m̀pọ̀tọ̀ ati Aláàfin Ajíbóyèdé.



Leyin ti Aláàfin Ajíbóyèdé papòdà ni Ọmọ rẹ ti n je Tẹ̀là Abípa bọ sori oye, oun ni o si gbe ijoba Ọ̀yọ́ kuro ni Ọ̀yọ́-Ìgbòho to o si pada gbe lọ si ibi ti a mọ si Oyo-Ile ti i se Ibùjókòó Ọ̀yọ́ tẹlẹ.



Ogun abẹ́lé lorisiirisi ni ilu Ọ̀yọ́ láàrin àwọn ilumoye tabi lati ọwọ awon ilu ti won n fe ominira ara won lo pada tu Ọ̀yọ́-Ilé paapaa julo ogun awon Fúlàní Ìlọrin. Àkọsílẹ R.C.C. Law (1971) Fi han pe awon ogun wonyi lo bi Ọ̀yọ́-Ilé wó pátápátá ni nnkan bi i ọdún 1836. Lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ni ìjọba Ọ̀yọ́ tun lo tẹ̀dó si ibi ti a mo si Àgọ́-d’ọ̀yọ́ pẹlu ìrànlọ́wọ́ Àtìbà ti o kọ́kọ́ jẹ ni Ọ̀yọ́ yìí. Àgọ́-d’Ọ̀yọ́ yii si ni Ijoba Ọ̀yọ́ fidi mule si titi di oni.



Ti a ba wa n soro lonii ni pa Ọ̀yọ́ tuntun yii, paapaa julo nipa awon Aláàfin ibẹ́, látorí Aláàfin Àtìbà tí ó jẹ́ àkọ́kọ́ Ọba níbẹ̀ láàrin ọdún 1837 si 1859 ni a ti maa bere, ibe naa ni a o si sètúpalẹ̀ lori ìwádìí nípa Oríkì won titi di ori Aláàfin tòní Ọba Adéyẹmí keta. (Ti o sẹ̀sẹ̀ wàjà)

Àtúnyẹwò pẹ̀lúu fífi àmì sí orí àwọn ọ̀rọ̀ láti ọwọ Adéyínká Ọlásúnkànmí Kásámasedáadáa

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *