OYO ALAAFIN ANTHEM

Ìlú Ọ̀yọ́ mo fẹ́ Ọ dé’nú
N ó sìn Ọ́, t’ọkàn t’ara
Ajísebí Ọ̀yọ́ làárí,
Ọ̀yọ́ kò gbọdọ̀ se bí oluko,
Ma f’owó mi pẹ̀lú ìmọ̀
Ọgbọ́n orí mi pẹ̀lú èrò
Gbó’go ìlú t’a bí mi ga

Egbe: Ìlú Ọ̀yọ́ ìlú Ọlọlá,
Ìlú Ọ̀yọ́ ìlú Ọlọ́ba
Ìlú Ọlọ́gbọ́n, ìlú Ọ̀mọ̀ràn
Ìlú t’Ọ́lọ́run se ní pàtàkì
Ìlú t’Ọlọ́run yọ́nú sí.

Ọmọdé Ọ̀yọ́ ẹ múra gírí
Àgbà Ọ̀yọ́ ẹ múra k’óle;
Ilẹ̀ ẹ wa ó l’ẹ́tù lójú
Nílé l’óko Ọ̀yọ́ kò s’ọ̀lẹ
Tí tẹ’pá mọ́’sẹ́ la fi ń yangàn
Isẹ́ ọwọ́ àwa l’àwá gbójúlé.

Nínú Ọba, Ọ̀yọ́ l’olórí
Aláàfin l’àgbà Ọba
Ìlú Ọ̀yọ́ gbayì ó sì m’ètò
Ẹsin iwájú kò gbọdọ̀ r’ẹ̀yìn
K’Ọ̀yọ́ sowọ́pọ̀
Ká le lo síwájúÌparí:

Wájú ni, èé wájú ni
Ìlú Ọ̀yọ́ kò ní rẹ̀hìn
Wájú la ó ma lọ

Wájú ni, èé wájú ni
Ìlú Ọ̀yọ́ kò ní rẹ̀hìn
Wájú la ó ma lọ


Wájú ni, èé wájú ni
Ilẹ̀ Ọ̀yọ́ kò ní r’ẹ̀yìn
Wájú la ó ma lọ“`

Composed by Baba Rtd. Arch-Bishop, Prince Ayọ̀ Ladigbolu


If you ever come across the melodious song of Oyo anthem, it was rendered and directed by
Sangodare Edward Oyedeji

SIDE NOTE:
Credits and accolades is hereby being given to all who have at one point or the other sang Ọ̀yọ́ anthem or worked on the song.

All the singers, dancers and producers.
We appreciate your creativities.

May our ancestors be pleased with you
(Àṣẹ🙏🏿)


Disclaimer
This written version is edited by
@Ajisebi Oyo Radio
Any errors or mistakes are unintended…

Original writer of the edited one unknown.


Ajísebí Ọ̀yọ́ làárí, Ọ̀yọ́ ò ní se bíi baba ẹnìkọ́ọ̀kan

@⁨LoomerTech⁩ ✌🏿

OYO ALÁÀFIN ANTHEM BY SANGODARE EDWARD OYEDEJI

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *